Àtúnṣe oríṣiríṣi ló ti wáyé lórí ìṣedéédé iná ìjọba l'Ékòó - Global Quest Magazine

Breaking

Contact us for your spiritual work,and solution

Contact us for your spiritual work,and solution
Contact us for your spiritual work, and solution call Golden Spiritual Hindu on 08038190202,08124446070


Tuesday, May 19, 2026

Àtúnṣe oríṣiríṣi ló ti wáyé lórí ìṣedéédé iná ìjọba l'Ékòó


               
Ọlaide Gold
Ijọba Ipinlẹ Eko ti kede eto tuntun to  ma mu ki iná ma wa yipo ọjọ fun wakati mẹrinlelogun  kaakiri ipinlẹ naa eyi to ma fopin si dakudaji ina mọnamọna.

Kọmiṣanna fun ẹka ileeṣẹ ijọba Eko  to n mojuto ọrọ agbara  ati Ohun Alumọni, Ọgbẹni Biọdun Ogunlẹyẹ, lo sọrọ yií ní Alausa, Ikẹja, lasiko to  n ṣalaye awọn iṣẹ ti iṣakoso Gomina Sanwo-Olu ti gbe ṣe lẹka ijọba naa fawọn oniroyin .

O sọ pe iṣakoso yii ti bẹrẹ awọn atunṣe lẹka ohun amuṣagbara, bakan naa ni eto ti to lati ṣamulo ofin to rọ mọ pipese ina Eko ọdun 2024, pẹlu erongba lati sọ ipinlẹ naa di ọkan lara awọn ọlọja ina mọnamọna to lágbára julọ nilẹ Afíríka.

Gẹgẹ bí Ogunleye ṣe sọ, ìjọba Eko fẹ ri daju pe ina fẹsẹ mulẹ ní ida marundinlọgọrun si ọgọrun ko  to di ọdun 2030.

O tun sọ pe LASERC ti bẹrẹ si fun awọn ile iṣẹ ni iwe aṣẹ , ti ijọba sì ma bẹrẹ eto fífi ẹrọ to n wọn iwọn ina tile kọọkan lo iyẹn mita sí gbogbo ile bẹrẹ lati oṣu Keje ọdun 2026.

Kọmiṣanna naa ṣalaye pe awọn ileeṣẹ apinnaka  olomìnira mejila lo wa nipinlẹ Eko, ti meje ninu wọn si n ṣiṣẹ daadaa lọwọlọwọ.

O tun jẹ ko di mimọ pe ina agboorun ẹgbẹrun mejilelogoji ni ẹka ileeṣẹ agbara ti pese sawọn adugbo  atawọn  gbajumọ ojuna marosẹ. O ni Ọsinitu Jẹnẹra to wa ni Gbagada ti n ri ina lo fun  wakati mọkanlelogun lojumọ.

Nípa ọkọ to  n ṣamulo afẹfẹ iyẹn CNG, Ogunlẹyẹ sọ pe ọkọ ojilenigba le mẹrin nijọba ti yi padà si eyi afẹfẹ gaasi bayii bakan naa lo ni ójuko mẹtdinlogun tawọn awakọ ti le ri afẹfẹ naa lo wa  kaakiri ti awọn mi-in ma kun ki ọdun 2026 tó parí.

O ní ìṣakoso Sanwo-Olu ni afojusun rere fun awọn olugbe ipinlẹ Eko lẹka agbara ati ohun amuṣọrọ.

No comments:

Pages