ÓRÍKÌ ÌLÚ Ọ̀YÁN - Global Quest Magazine

Breaking

Contact us for your spiritual work,and solution

Contact us for your spiritual work,and solution
Contact us for your spiritual work, and solution call Golden Spiritual Hindu on 08038190202,08124446070


Monday, July 31, 2023

ÓRÍKÌ ÌLÚ Ọ̀YÁN


Ìyẹ̀rú Ọ̀yán; mo fínrà mo jàre

Ọmọ a bí l’Ọ́yàn án ,ọmọ a pègbè pọ̀

Ọmọ a ṣe gbẹ́dẹ́ relé ọba

Àjàlú pòrògòdò l’Ọ́yàn

Ọmọ Ọlọ́yàn ẹgbẹ̀rún Agbe

Ọmọ Ọlọ́yàn ẹgbẹ̀rún Àlùkò

À t’Agbe,a t’Àlùkò

Ní í bẹ nígbèrí ẹ̀gún nibi t’ómi ń sun s’Áyaba lẹ́nu

Ògèré wá jẹun ò dénú

Ògèré dá là l’Ọ́yàn

Ẹ jẹ́ k’Ólóunjẹ máa mú oùnjẹ rẹ jẹ

Ọ̀yún sì po o

Jẹ́ k’Ólóúnjẹ má a mú oúnjẹ rẹ jẹ

Ọ̀yún sì mẹ́rẹ́

Mo mẹ́rú piyamọ, mo fàlàlà joyè mọ̀jẹ̀

Níjọ́ ọ̀run ń yaábọ̀ lẹ́yìnkùlé ọba

Ní jọ́ ọ̀run n yaábọ̀ l’Ájàṣẹ́ ilé

Ọlọ́ya ń ki Ọya lóde ìsálúpo

Oní pẹ̀là ń ki pẹ̀là l’Ọyàn

Alágídí ti m’ágídí rẹ̀ so

Ọ̀yán ò gbudọ̀ jẹ̀bi ọ̀rọ̀

Torí ọgbọ́n yí wọn nínú po

Ǹlẹ́ ọmọ a bí l’Ọ́yàn án ọmọ a pègbèpọ̀

 

 


No comments:

Pages