US–Israeli–Iran:Agbarijọ awọn Imaamu rọ àwọn aráàlú láti yẹra fún ìfẹ̀hónúhàn - Global Quest Magazine

Breaking

Contact us for your spiritual work,and solution

Contact us for your spiritual work,and solution
Contact us for your spiritual work, and solution call Golden Spiritual Hindu on 08038190202,08124446070


Monday, March 9, 2026

US–Israeli–Iran:Agbarijọ awọn Imaamu rọ àwọn aráàlú láti yẹra fún ìfẹ̀hónúhàn


Ọlaide Gold

Agbarijọ awọn Imaamu nipinlẹ Eko, ti rọ awọn ọmọ orileede Naijiria lati yẹra fun  ifẹhonuhan to le pa alaafia orileede lara, wọn ṣe atẹnumọ ọrọ wọn pe; asiko adura ati ironupiwada yii ko faaye gba ifẹhonuhan rara.

Igbesẹ yii waye latari ipe ifẹhonuhan kan tawọn kan pe kaakiri orileede Naijiria lati tako bi orileede America ati Israeli ṣe ju ado oloro si ilẹ Iran, eyi to ṣokunfa iku adari ilẹ, Ali Khamenei.

Sheikh Abdul Rahman Ahmad, aṣoju ajọ Ansarudeen Society, lo bẹbẹ naa lorukọ agbarijọ awọn Imaamu lasiko eto Tafsir Ramadan ọdun 2026, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun Tuside, nile ijọba ni  Ikẹja.

Ahmad jẹ ko di mimọ pe, ṣe lo yẹ kawọn eeyan lo asiko aawẹ Ramadan ati aawẹ awọn onigbagbọ lati gbadura fun alaafia ati iṣedeede ipinlẹ Eko ati orileede Naijiria.

O ni, ifẹhonuhan kii bi nnkan rere nitori naa kawọn araalu maṣe darapọ mọ nnkan to le mu idaamu ba adugbo kọọkan.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, asiko adura ni a wa yii, ki i ṣe asiko ifẹhonuhan rara nitori naa ẹ jẹ ka gba alaafia laaye. Asiko yii lo yẹ ka sun mọ Ọlọrun Ọba Allah julọ ki a le ri aanu gba latọdọ rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe orileede Naijiria ni awọn adojukọ kan lọwọlọwọ paapaa ọwọngogo to gbode ṣugbọn o yẹ kawọn eeyan mọ pe, ija to n ṣẹlẹ laarin awọn ilu alagbara lagbaye naa yoo jẹ kowo epo tun lọ soke si i, o ni, o yẹ kawọn eeyan lọ mọ eyi ki wọn ma lọ bẹrẹ ifẹhonuhan ti ko lẹsẹ nlẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe, bo tiẹ jẹ pe, inu awọn ko dun bi wọn ṣe n ṣekọlu sawọn ọmọ iya awọn loke okun ṣugbọn nnkan teeyan ko ba le yanju ko gbọdọ da kun un.

O ni kawọn eeyan maṣe bẹrẹ nnkan ti wọn ko le pari nitoripe rabọrabọ ọrọ ifẹhonuhan fopin si ọlọpaa adigboluja ‘EndSARS’ ko tii tan nilẹ.

Ahmad wa rọ awọn adari ẹsin kaakiri orileede Naijiria lati ba awọn olujọsin wọn sọrọ, o ni ki wọn ran wọn leti pe ifẹhonuhan kii bimọ rere, O ni kawọn eeyan gba alaafia laaye lo tọ, eyi lo ma je ki iṣọkan fẹsẹmulẹ kaakiri orileede.


No comments:

Pages